Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Ọdún dé! Sultan Sokoto ti rí òṣùpá, kéde ọjọ́ Ẹ̀tì gẹ́gẹ́ bí ọdún Eid al Fitr

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Sultan ti ilu Sokoto to tun jẹ adari gbogbo ẹlẹsin musulumi lorilẹede Naijria ti kede pe wọn ti ri oṣupa eyi ti gbogbo mumini ati mumina ti n reti lati Ọjọbọ tii ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn ti aawẹ Ramadan ti bẹrẹ.
Igbimọ to n ri si wiwa oṣupa ni Naijiria lo kede opin aawẹ Ramadan ati ọdun Salah.
Awọn musulumi ti n woye tẹlẹ pe boya ọdun naa yoo bọ ọjọ kọkanlelogun tabi ọjọ kejilelogun oṣu kẹrin ọdun yii.
Bakan naa, ijọba orilẹede Naijiria ti kede pe isinmi ọdun yoo waye ni ọjọ Ẹti ọjọ kọkanlelogun ati ọjọ Aje ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹrin ọdun 2023 lati ṣaami ayẹyẹ ọdun Eid al fitr.
Ki ni ọdun Eid al Fitr?
Eid al fitr ni ọdun ti awọn musulumi tun maa n pe ni ayẹyẹ ọdun itunu aawẹ.
O maa n jẹ akoko ọdun alajọyọ eyi to fihan pe opin aawẹ ti de eyi ti wọn ti n gba lati oṣu kan lai jẹun tabi mu ohunkohun lati aarọ ti irọlẹ.
Asiko Ramadan jẹ ọkan lara opo pataki marun to di ẹsin Islam mu bẹẹ si ni ayẹyẹ ọdun Eid ṣe pataki lati pari asiko aawẹ gbigba naa ati lati pa iwa da to fi mọ ṣiṣe itọrẹ aanu.
Gbogbo ẹbi, ara ati ọrẹ lo maa n kora jọ lati ṣe ajọyọ, wẹjẹwẹmu ati ipifunni lasiko yii pẹlu oniruuru imura to ta lẹnu.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pín ìwé sọ̀wédowó N20.9M owó adójútòfò

Oríṣun àwòrán, Oyo Police
Àkọlé àwòrán, Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Giwa ile iṣẹ ọlọpaa orilẹ-ede yii Usman Baba ti fi iwe sọwedowo ogun milliọnu fún awọn molebi awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ọlọpa to padanu ẹmi wọn lẹnu iṣẹ ni ipinlẹ Oyo.
Awọn to gba iwe sọwedowo ọhun ni awọn ibatan ati molebi awọn ọlọpa to padanu ẹmi wọn lẹnu iṣẹ. Awọn idile oṣiṣẹ ọlọpa lo n jẹ igbadun eto adojutofo ti giwa ile iṣe ọlọpa ṣe fun awọn oṣiṣẹ ọlọpa.
Kọmisona ọlọpa fun ipinlẹ Oyo,Adebowale Williams ẹniti o ṣoju Giwa olopaa ninu eto ọhun sọ pe,eto naa wa ni ibamu pẹlu ileri ti giwa olopaa ṣe lati mu igbe aye awọn oṣiṣẹ ọlọpa rẹwa si yala awọn to ti ku ati awọn to fẹyìntì lẹnu iṣẹ.
Adebowale rọ awọn to jẹ anfani owo adojutofo ọhun lati ṣe amulo rẹ daradara kí wọn si mojuto awọn dukia ati idile ti oloogbe fi saye lọ.
Lara awọn to jẹ anfani eto ọhun, dupẹ lọwọ Giwa ile iṣẹ ọlọpaa fun afojusun ọhun,wọn ṣeleri lati lo owo naa daradara pẹlu bi owo ọhun ṣe de si asiko ti ilakoja idile awọn pọọ .
'Ìdí rèé tí mo ṣe lu ìyàwó mi ní àlùbami'

Oríṣun àwòrán, Google
Micheal Agosu ni wọn ti fẹsun kan pe oun naa iyawo nina bara nilẹ iṣẹ ọlọpa to wa ni ogijo ipinlẹ Ogun.
Micheal nigba ti oun jẹwọ fun awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ọlọpa ni bẹẹ lọrọ ri,ṣugbọn iyawo oun lọ fa nitori oun fi orun dun n.
Baba ọlọmọ mẹrin ọhun ni o fi lulu ṣe ti iyawo rẹ Kafiat Salami ni ile wọn lagbegbe Escoba ni Ogijo,oni "Gbogbo igba ni iyawo mi ń bere owo ".
"Ko gba ka ṣere ifẹ rara,gbogbo alẹ ni oun ma n wọ ṣokoto sun,nigba ti a ba pari ere ifẹ nisẹ ni yoo tun wọ ṣokoto kí n ma ba tun sun mọ".
Kafiat ninu ọrọ rọ ijọba lati gba oun ki Micheal to gba ẹmi oun. Kafiat ọmọ bibi ilu Ibadan ni,"lati ọdun kẹrinla ti mọ ti wa ninu igbeyawo ni oun ti n na mi,koda nigba ti mo loyun akọbi mi ,nina ni oun na mi n".
Kafiat ni "Jẹjẹ ni mọ n fọ aṣọ nilẹ,nisẹ lo de to ṣi ni oun yo na mi pa,igi àti irin lo fi daa saria fun mi,koda bí ẹjẹ ṣe bomi to nina ni oun na mi".
Nigba ti o un tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ Kafiat ni, "lati ọdun mẹrinla ta ti ń gbe pọ bi lọkọ laya ko ti san owo ori mi,Iya baba mi nikan lo mọ nipa ibasepo wa,mo bímọ fun tan kí baba mi to jade laye to mọ ".
Ọmọ Cotonou ni ọkọ mi sugbọn iṣe kapenta ni oun ṣẹ ni mushin,ẹ bami fòpin ṣi ibasepoyii.
Babaláwo so ọmọ rẹ̀ méjì mọ́lẹ̀, fi ebi pa wọ́n ku
Awakọ̀ Kẹ̀kẹ́ Maruwa gún èrò ọkọ̀ rẹ̀ pa nítorí ₦50, aráàlú sọ òun náà lókùta pa

Oríṣun àwòrán, Daily Trust
O kere tan, eeyan meji ti jade laye niluu Yenagoa, nipinlẹ Bayelsa lẹyin ariyanjiyan kan to waye laarin awakọ kẹkẹ Marwa ati ero ọkọ rẹ.
Iroyin ni wahala naa bẹrẹ lẹyin ti ero ọkọ naa san ₦100 fun awakọ kẹkẹ ọhun nigba to bere fun ₦150.
Igba ti ija bẹ silẹ laarin awọn mejeji ni awakọ kẹkẹ ọhun gun ero ọkọ rẹ lọbẹ, eyii to yọri si iku rẹ.
Ko pẹ lẹyin naa lawọn eeyan to wa lagbegbe Yenizue-Epie ti iṣẹlẹ ọhun ti waye yabo ibi to ti ṣẹlẹ ti wọn si sọ awakọ kẹkẹ naa lokuta pa.
Iṣẹlẹ iṣekupani naa tun yọri si rogbodiyan mii laarin awọn ọmọ Hausa to wa ni Yenagoa atawọn eeyan to n gbe ni Yenizue-Epie.
Wayi o, gomina ipinlẹ ipinlẹ Bayelsa, Douye Diri ti pe ipade alaafia laarin awọn ẹya Hausa atawọn olori Yenizue-Epie lọna ati yanju wahala ọhun.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ̀ tó èèyàn 80 ti jáde láyé níbi tí wọ́n ti fẹ́ gba ẹ̀bùn Ramadan

Oríṣun àwòrán, AFP
O kere tan eeyan mejidinlọgọrin ti gbẹmi mi nibi ikọlukọgba ni ile ẹkọ kan ni olu ilu Yemen, Sanaa lasiko ti wọn n pin nnkan iranwọ asiko Ramadan.
Gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ṣe sọ, fọnran to jade ṣafihan bi aduru ero eeyan ṣe rọ digba digba lai ribi rin si ni agbe Bab al-Yemen ni ilu naa.
Ọgọọrọ ni iroyin sọ pe o rọ lọ si ile ẹkọ naa nirọlẹ Ọjọbọ lati lọ gba ẹbun owo ọfẹ to to $9 (£7; €8) fun eeyan kọọkan.
Fidio to gba ori ayelujara kan fihan bi awọn eeyan ṣe n pariwo lohun rara ti ọpọlọpọ oku si sun silẹẹlẹ ti ko si ẹni to gbe wọn kuro. A ri awọn mii ti wọn gbiyanju lati ṣeranwọ.
Nibayii ọwọ Ọlọpaa ti tẹ oniṣowo meji kan to ṣe agbekalẹ eto ẹbun ọfẹ naa ti iwadii si ti n lọ lọwọ, minisita fun ọrọ abẹle sọ eyi.

Agbẹnusọ kan fun ileeṣẹ naa da ẹbi ikọlukọgba ati titẹ eeyan mọlẹ yii ru “bi awọn kan kan ṣe maa n pin owo lai ṣe aato pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ.
Ọpọlọpọ lo tun farapa nibẹ ti awọn mẹtala si wa ni ipo to buru jai gẹgẹ oṣiṣẹ eleto ilera ṣe sọ ọ ni Sanaa.
“Awọn obinrin atawọn ọmọde wa lara awọn to gbẹmi mi,” oṣiṣẹ alaabo Houthi kan sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP amọ ẹni naa ko fẹ dfarukọ ara rẹ tori o ni wọn ko fun oun laṣẹ lati sọrọ.
Ileeṣẹ Iroyin Associated Press naa jabọ ti wọn sọ pe awọn oṣojumikoro meji kan ni awọn ajijagbara Houthi kan n yinbọn sinu afẹfẹ lojuna ati dari awọn ero to wa nibẹ.
“Ibọn naa lo ba opo ina kan to si di pe o bugbamu. Eyi tun da kun ibẹru to si mu ki awọn eeyan maa sare, maa tẹ ara wọn mọlẹ”.
Iroyin ni awọn ẹgbẹ Houthi ti gba pe awọn yoo san $2,000 (£1,600) fun idile kọọkan to padanu eeyan nibẹ nigba ti awọn to farapa yoo gba nnkan bii $400 (£322).
Iṣẹlẹ yii waye ni o ku ọjọ diẹ ki aawẹ Ramadan pari.
Èrò India yóò pọjù China lọ kọdún 2023 tó dópin - UN

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àkọlé àwòrán, India Orilẹede India lo ṣeeṣe ko tayo orilẹ-ede China gẹgẹ bi orilẹ-ede ti ero rẹ pọ julọ lagbaye ninu oṣu kẹfa ọdun yii, gẹgẹ bi atẹjade kan ti ajọ agbaye United Nations filede.
Apapọ awọn olugbe India lo ṣẹṣẹ ko to billiọnu 1.4286 si billiọnu meji le 2.9 eyi ti yo mu ju orilẹede China lọ to jẹ billiọnu 1.4257
Awọn orilẹ-ede to wa ni ẹkun asia ni o ko ida kan ninu ida mẹta apapọ gbogbo olugbe agbaye lati aadọrin ọdun sẹyin.
Orilẹ-ede China ni adinku ti n ba awọn olugbe ibẹ,eyi yo jẹ igba akọkọ lati ọdun 1961 ti akọsilẹ awọn olugbe China yoo dinku.
Akọsilẹ ajọ agbaye to risi eto ikaniyan lo foju woo bẹẹ nitori,ko ti si eto ikaniyan kankan lorilẹede Indian lati ọdun 2011.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti Patrick Gerland to jẹ ọga lẹka to risi eto ikaniyan fun ajọ ìṣọkan agbaye ṣe pẹlu ile iṣe iroyin BBC ó ni,"gbogbo akọsilẹ ati iwadii tọka si wi pe akọjọpọ awọn olugbe India pọ si ṣugbọn a ti le fidi iye wọn gangan mulẹ".
Ninu oṣu kọkanla ọdun to kọja ni akọsilẹ gbogbo awọn eeyan agbaye wọ billiọnu mẹjọ.
Orilẹ-ede India ati China ni adinku ti ba ọna ibimo sii wọn,lati ọdun to un bọ apapọ awọn olugbe China yo dinku sii,botilẹ jẹ wi pe China ti ń fopin sii ilana kí idile kan bi ọmọ kan.
Lorilẹede Indian adinku naa ti ba ọna ọmọ bibi nitori wi pe tẹlẹri obinrin kan a ma bi ọmọ marun-un tàbí ju bẹ lo,ṣugbọn lọwọ yii, awọn obinrin India ko bi ju ọmọ meji sì mẹta lọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti ajọ to risi eto ikaniyan ṣe ni India,ọpọ awọn to sọrọ ni bi onka awọn olugbe India ṣe n pọsi, ko yẹ ko ká awọn eeyan lara,Nitori o yẹ ki wọn kaa sì ilọsiwaju àti idagbasoke ni India.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àkọlé àwòrán, India Káwọn mùsùlùmí wojú ọ̀run fún oṣù tuntun Shawwal láti parí àwẹ̀ - Sultan Sokoto

Awọn ẹlẹsin musulumi lorilẹede yii ni wọn ti ke si lati foju sọna wa oṣupa Shawwal 1444 AH lati ọjọ, Ọjọbọ eyi ti yoo safihan ifopin si awẹ gbigba ọranyan fún awọn musulumi jakejado orilẹ-ede yi.
Sultan Sokoto , Alhaji Sa’ad Abubakar,ẹni to tun jẹ olori awọn ẹlẹsin musulumi ni orilẹ-ede yii lo fi iroyin naa lede latọwọ amugba lẹgbẹ rẹ to risi ọrọ ẹṣin, Ọjọgbọn Sambo Junaidu.
Ninu atẹjade ọhun Sultan ni,"Eyi ni lati kede fún awọn musulumi ododo wi pe lati Ọjọbọ ọṣẹ yii,to tun jẹ ọjọ ti awẹ yoo di ọjọ kokaan din logbon ni yoo jẹ ọjọ ti wọn o wo oorun Shawwal 1444 AH.
Sultan gbadura ki Olorun ka awẹ naa si ibukun fun awọn ẹlẹsin musulumi jakejado Naijiria.
Riri oṣupa ni yoo mu opin baa awẹ gbigba eyiti o jẹ ọranyan fun awọn musulumi,Shawwal jẹ oṣu Kẹwa ninu Kalẹnda awọn musulumi.
Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ Ẹtì ọ̀sẹ̀ yìí àti ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀ fún ìsinmi ọdún ìtúnu àwẹ̀

Oríṣun àwòrán, Ministry of Interior Nigeria
Ijọba apapọ ti kede ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelogun, ati ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu yii gẹgẹ bii ọjọ isinmi ọdun itunu awẹ.
Minisita fun ọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Aregbesola, lo fi ikede naa sita niluu Abuja.

Oríṣun àwòrán, Ministry of Interior Nigeria
Aregbesola rọ awọn Musulumi lati lo akoko ọdun naa lati gba alaafia laaye laarin ara awọn atawọn ọmọlakeji wọn.
O tun rọ wọn lati fi akoko ọdun itunu awẹ ọhun gbadura fun eto abo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.
Lẹyin naa lo gbadura pe wọn yoo ṣe ọpọ ọdun naa nile alaaye.
A kò rí oúnjẹ tàbí omi mu- Àwọn tó há sínú ilé ìjọsìn ní Sudan figbe ta!

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn eniyan ti ke gbajare sita pe iya n jẹ awọn eniyan to ha ninu ija to n lọ lọwọ ni Sudan.
Arabinrin lati ilẹ Russia to ha sí ile ijọsin awọn ara ilẹ Greece ti ni awọn marundinlogun miran wa pẹlu oun ninu ile ijọsin ti wọn ha sí.
O ni awọn ko si ni ina, omi tabi ounjẹ to fi mọ awọn ọmọde to wa laarin wọn.
Lasiko to n ba BBC sọrọ, o ni oun lọ ẹṣin ọdun Ajinde ni awọn bẹrẹ si ni gbọ Iro ibọn to n dun kíkan.
Awọn ara ilẹ Greece ti wọn gbiyanju lati sa kuro ninu ile ijọsin nigba tí ìjà náà bẹrẹ ni wọn fi ara gba ọta ibọn.
"Wọn gbe wọn lọ sí ile iwosan to sunmọ ibẹ amòͅ wọn nilo iṣẹ abẹ ti wọn sì máa gbé wọn padà wa si ile ijọsin nitori wọn fẹ ti awọn ile iwosan naa pa."
Yatọ sí ọmọ mi, awọn ọmọ wẹwẹ meji miran wa ninu awọn ti wọn ha sibẹ lati bíi ọjọ marun - ti ibọn si ni dun kikan."
Fún bí ọjọ diẹ, a si ni ounjẹ ati omi fun awọn eniyan ni ile ijọsin amoͅ ko si ounjẹ mọ bayii, to fi mọ epo bentiroolu fún ẹrọ alupupu nitori wọn ti sekolu sí ina ọba, ti ko si ina."
Bakan naa ni àwọn ara ilẹ Ethiopia ati Sudan pẹlu awọn tó há sí ilé ijosin náà.
Arabinrin naa wa kesi ti wọn jọ wa ni oju opo WhatsApp rẹ lati ri pe wọn pin iroyin naa jale jako.
Ìjàmbá Bọ́ọ̀sì BRT àti ọkọ̀ Danfo gbẹ̀mí Dẹ́rẹ́bà, aráàlù sọ iná sí BRT!
'Ẹni tí kó bá wà ní mímọ́ kò lè sin Sango, bí Olúkòsò ṣe máa ń búyọ l'óru láti kọ̀yà f'éèyàn rèé'
Atiku kí Fintiri kú oríire, Ó ní àwọn afipágbàjọba gbìyànjú ṣùgbọ́n ...
Ìdí nìyíí tí ọkùnrin kò tíì lè lo òògùn ìfètòsọ́ͅmoͅbíbí títí di àsìkò yìí
Ìjọba Nàìjíríà dá àwọn ọmọ Nàìjíríà 107 tó há sí Libya padà sílé

Oríṣun àwòrán, Nema
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, NEMA ti da awọn ọmọ Naijiria to le ni ọgọrun un to ha si orilẹede Libya pada .
Awọn eeyan naa ni ọkọ ofuurufu Al-Buraq pẹlu nọmba Boeing 737-80,55A-DMG lo balẹ si papakọ ofurufu Muritala Muhammed to wa ni Ikeja.
Ọga agba ajọ NEMA Mustapha Ahmed eniti Aziz Afunku soju fun ni ọmọ orilẹ-ede yi to to ọkan din ni ọtalenigba ni ajọ ọhun ti da pada wa so orilẹede Naijiria pada ninu oṣu kẹta ọdun yii nikan.
Ninu oṣu kẹrin ọdun yii, akọsilẹ ajọ NEMA fihan wi pe ọmọ orilẹ-ede yii bi ọkan din ni ọtalenigba ni wọn ti se iranlowo fun lati dapada wale si ile.
Lati ọdun 2017 ni ajọ agbaye to n ṣe abojuto atipo ti ń ṣe iranlọwọ lati da awọn ọmọ orilẹede to wa nile okere pada sile.
Lara awọn to tekọ leti pada ni ọmọde kùnrin mẹrin ati ọmọde bìnrin mefa.
A ti gbé ìlànà ọlọ́dún márùn-ún kalẹ̀ lórí ètò ààbò - Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Others
Àkọlé àwòrán, Aregbesola, Civil Defense Ijọba apapọ orilẹede yi ti gbe ilana ọlọdun marun-un kalẹ lati gbogun ti iṣoro aisi aabo to peye lorilẹede Naijiria.
Nigba to n ṣiṣọ loju awọn ilana ọhun, Ọgbẹni Rauf Aregbesola ẹniti o jẹ minisita fun ọrọ abẹle ni, awọn ẹka to wa labẹ ile iṣe ọrọ abẹle ni wọn yo lo lati gbogun ti iṣoro aisi abo to peye.
Ninu ọrọ rẹ Aregbesola ni " ile iṣe ijọba to risi ọrọ abẹle ko ipa ribiribi ninu ipese abo to daju".
Awọn ileeṣẹ ijọba to wa labẹ ẹka to risi ọrọ abẹle ni ile iṣe to risi ìwọle wọde, Ajọ abo ara ẹni labo ilu (Civil Defense), ajọ to risi ọgba ẹwọn(Nigeria Correctional Service.) ati ajọ to gbogunti ajakale ina(Federal fire Services).
Gomina ipinlẹ Osun nígbà kan rí Rauf Aregbesola ni,'asiko ti to bayii lati ni afoju sun ọlọdun marun-un fun awọn ẹka ijọba to wa labẹ ile ise to risi eto abẹle.'.
Aregbesola ni akọsilẹ ijọba ti fihan wi pe ẹka mẹrin to wa labẹ iṣakoso ile iṣe to risi ọrọ abẹle ni ko ni, ilana atẹle to daju lati igba ti wọn ti ṣe ìdásílẹ̀ wọn.
O ni asiko ti to lati tẹlẹ ilana tuntun ọlọdun marun-un ki eto aabo le gboro sì ni orilẹede Naijiria.
Ahmadu Fintiri ti ẹgbẹ́ òsèlú PDP wọlé sáà kejì gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa

Oríṣun àwòrán, @Faridatu001
Gomina ipinlẹ Adamawa, Ahmadu Umaru Fintiri, ti wọle gẹ bii gomina ipinlẹ naa fun saa keji.
Fintiri bori ibo ọhun pẹlu ibo ti iye rẹ jẹ 430,861 nigba ti ti oludije ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Sẹnetọ Aisha Dahiru ni ibo ti iye rẹ jẹ 396,788.
Ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta ti a wa yii ni eto idibo gomina ọhun waye amọ idibo naa ko kẹsẹ jari, eyii to mu ki wọn kede atundi ibo to waye lopin ọsẹ to kọja.
Eto idibo ọhun lọ ni irọwọrọsẹ ṣaaju ki aṣoju INEC nipinlẹ ọhun to kede pe Aisha Dahiru, ti ọpọ mọ si Binani lo jawe olubori, eyii to da wahala silẹ.
Amọ aṣoju ajọ INEC ni ipinlẹ ko laṣẹ labẹ ofin lati kede ẹni to jawe olubori nigba ti wọn ṣi n ka ibo naa lọwọ.
Ọpọ lo gbagbọ pe Aisha Dahiru, ti INEC kọkọ kede ṣaaju yii, ni yoo jẹ gomina obinrin akọkọ ni Naijiria, amọ o lulẹ.
Oͅlóͅpàá ti fi èͅsùn kan Andrew Lester tó yìnboͅn lu òͅdoͅmoͅdé tó sͅèsͅì kan ilèͅkùn rèͅ

Arakunrin kan ni ilu Missouri, lorileͅede Ameͅrika ni woͅn ti fi eͅsun kan pe o yinboͅn lu oͅdoͅkunrin kan nitori o sͅesͅi kan ileͅkun reͅ.
Arakunrin Andrew Lester to jeͅ eͅni oͅdun meͅrinleloͅgoͅrin ni woͅn fi eͅsun lilo
iboͅn loͅna ti ko toͅ, to si fa ipalara kan.
Mr Lester to jeͅ alawoͅ funfun lo yinboͅn lu Ralho Yarl to jeͅ alawoͅdudu, eͅni oͅdun meͅrindinlogun ni ori ati apa.
Adupe pe oͅmoͅ naa wa laaye, ti oͅloͅpaa ti o fi eͅsun si ni o seese ki eͅsun naa ni oͅroͅ eͅleͅyameͅya ninu.
Amoͅ ko si ikorira tabi eͅya ninu eͅsun ti woͅn fi kan an.

Oríṣun àwòrán, Others
Ileesͅeͅ oͅloͅpaa koͅkoͅ ti oͅkunrin naa moͅle amoͅ woͅn tu sileͅ, ti awoͅn eniyan si beͅreͅ si ni fi aidunnu woͅn han.
Agbeͅjoͅro idile Yarl, ni o lodi si ofin ki eniyan dede yinboͅn lu eͅlomiran nitori o kan ileͅkun reͅ.
Amo eͅni ti woͅn fi eͅsun kan naa ni oͅdoͅmoͅde naa koͅkoͅ n kaakiri eͅyibkule oun, ki o to kan ileͅkun.
Awoͅn obi reͅ ni awoͅn aburi re lo wa loͅ si agbegbe 115th Street, to si yeͅ ko loͅ si agbegbe 115th Terrace.
Leͅyin ti arakunrin Andrew yinboͅn lu tan ni nkan bi aago meͅwa, lo wa ile miran si pe ki woͅn saanu oun.
Woͅn ko si oͅroͅ kankan ti onile soͅ lati beere loͅwoͅ oͅmoͅ naa ki o to yin iboͅn lu.
Oͅjoͅ Aiku lo kuro ni ileewosan ti o si n gba itoͅju ni ile, ti awoͅn obi reͅ si ni inu awoͅn dun si eͅsun ti woͅn fi kan arakunrin to yinboͅn lu oͅmoͅ naa.
Nibayii, awoͅͅn araalu ti n da owo joͅ fun itoͅju oͅmoͅ naa, ti aareͅ Joe Biden si ti pe awoͅn moͅleͅbi lati ba woͅn kèͅun peͅlu ileri pe ki woͅn wa si ile aareͅ White House ni kete ti ara oͅmoͅ naa ba ti da tan.
Kà nípa Bíṣọ́ọ̀bù Oluwafeyiropo tó r’ẹ́wọ̀n he fẹ́sùn ìfipá bá ọmọ ìjọ rẹ̀ méjì lòpọ̀