Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Mo lo ọjọ́ mẹ́ta ní àhámọ́ àwọn ajínigbé, ojú mi rí tó
Adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Kwara, Sikiru Oyinloye dágbére fáyé

Oríṣun àwòrán, Others
Adajọ ni ile ẹjọ gíga ipinlẹ Kwara, Onidajọ Sikiru Oyinloye tí jade laye.
Oyinloye jade laye lana ọjọ Aiku lẹyin aisan ranpẹ to sẹlẹ si.
Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sapejuwe iku Onidajọ naa gẹgẹ bii ohun to duni lọpọlọpọ ati pe adanu nla lo jẹ fun ipinlẹ Kwara.
"A darapọ mọ ile ẹjọ gíga ipinlẹ Kwara ati Naijiria lati daro iku Onidajọ Oyinloye.
"A ba awọn mọlẹbi kẹdun, awọn eeyan ìjọba ibilẹ ìsìn ati gbogbo awọn to n daro lori Iku Onidajọ Oyinloye.
"A gba ladura pe Ọba Allah tẹ wọn si afẹfẹ rẹ, ko si tun duro ti mọlẹbi ti wọn fi silẹ."

Oríṣun àwòrán, others
Èèyàn méje pàdánù ẹ̀mí wọn, mẹ́rìnlá sí farapa yánayàna ní òpópónà Eko si Ibadan

Oríṣun àwòrán, others
O to eeyan meje to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ loju opopona marosẹ Eko si Ibadan lọjọ Aiku.
Eyi lo wa ninu atẹjade ti agbẹnusọ ajọ oju FRSC, Bisi Kazeem fi ransẹ si awọn akọroyin.
O ni ọkọ ayọkẹlẹ Mazda funfun pẹlu nọmba idanimọ BDG993YG lo takiti lẹyin ere asapajude.
"Eeyan mẹrinla lo farapa, agbalagba ọkùnrin mẹrin, agbalagba obìnrin marun-un, ọmọdekunrin meji ati ọmọdebinrin mẹta.
"Awọn eeyan meje miiran padanu ẹmi wọn, agbalagba ọkùnrin meji, agbalagba obìnrin mẹta ati ọmọdekunrin meji."
Ilé alájà mẹ́ta mìíràn tún dàwó ní Ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, LASBCA
Ile alaja mẹta ti wọn kọ lọwọ lo ti dawo ni agbegbe Ladipo Oluwole ni Apapa nipinlẹ Eko.
Iṣẹlẹ ọhun lo waye lọjọ Aiku, ti ajọ to n risi ile kikọ nipinlẹ Eko si ti balẹ si agbegbe naa.
Ninu atẹjade tí ajọ LASBCA fi ransẹ si awọn akọroyin, igbakeji oludari ajọ ọhun, Mukaila Sanusi fẹsun kan awọn abanikọle pe wọn kuna lati da wọ isẹ lẹyin tí ìjọba palasẹ fun wọn.
Bakan naa ni Sanusi fikun pe ko si iroyin kankan pe ẹmi sọnu níbi iṣẹlẹ naa.
Iṣẹlẹ yii lo waye lẹyin wakati mẹrinlelogun ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ṣe abẹwo si ile alaja meje to dawo lọjọ Kejila osu kẹrin ọdun 2023.
A ti kó àwọn ènìyàn wa kúrò ní Sudan – Olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Oríṣun àwòrán, Reuters
Olootu ijọba Ilẹ Gẹẹsi, Rishi Sunak ti kede pe awọn ti ko gbogbo ọmọ Ilẹ Gẹẹsi to n ṣiṣẹ ni Sudan kuro nibẹ lọwọlọwọ.
Eyi ko ṣẹyin ija to n waye nibẹ to si ti gbẹmi ọpọ eniyan.
Bakan naa ni awọn araalu ha si ile ijọsin ati awọn agbegbe naa lai si ina ọba, omi tabi ounjẹ.
Ọga Sunak ni iṣẹ ṣi n tẹsiwaju lati ri pe gbogbo awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi to wa nibẹ ni awọn doola ẹmi wọn.
Awọn ti wọn ko kuro nilẹ Sudan naa ni wọn ko lọ si papakọ ofurufu to wa ni ode ilu Khartoum lati kuro ni inu ilu naa ni oru mọju.
Ọṣẹ to kọja ni ija bẹ silẹ ni Khartoun laarin awọn ọgagun meji ti wọn n tako ara wọn gẹgẹ bi adari lorilẹede naa.
Igun ikọ ọmọogun to gbajọba lo n koju ikọ RSF to n lọgun lati gba ijọba.
Dúkìá ṣòfò bí báràkì ọlọ́pàá ṣe dàwó ní Ibadan
Ọkùnrin tó ń bá òkú gbé láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn kó sí gbaga ọlọ́pàá
Ilé ìgbé Ọlọ́pàá dàwó n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, Twitter
Abala ile igbe ni ileeṣẹ Ọlọpaa ni Sango niluu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo lo dawo lana.
Ninu fọnran kan to gba orí opo ayelujara Twitter lo safihan ile alaja mẹta naa to ti dawo.
Bakan naa ni fọnran fihan pe ọpọ awọn eeyan lo ha sinu ile ọhun.
Skip X postAllow X content?Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ẹ gbádura fún Tinubu – Yari

Oríṣun àwòrán, Google
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Zamfara, Abdul'aziz Yari ti ke si awọn musulumi lasiko ayẹyẹ odun itunu awẹ lati gba adura fun Aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan, Bola Tinubu.
Yari sọ eleyi lasiko to n gba awọn akọroyin lalejo ni ile rẹ niluu Talata - Mafara nipinlẹ Zamfara.
Bakan naa lo rọ àwọn Naijiria lai yọ ẹya tabi ẹṣinkankan silẹ lati ri daju pe wọn gba adua fun aseyọri Tinubu.
"A ni lati gba adura sì Ọba Allah lati se atilẹyin fun Aarẹ lati le ṣe gbogbo ohun to seleri lati se fun awọn araalu.
"Ani igbagbọ ninu Tinubu, a ni igbagbọ o le tun Naijiria ṣe.
"Gbogbo ero ọkan APC ni lati mu igbasoke de ba orilẹede Naijiria."
Sanwo-Olu pàṣẹ kí wọ́n da ilé mẹ́ta wó ní Banana Island

Oríṣun àwòrán, Facebook/BabajideSanwoolu
Gomina ipinlẹ Eko. Babajide Sanwo-Olu ti palasẹ pe ki wọn da ile gbe mẹta ọtọọtọ, to jẹ alaja meji wo ni agbegbe Banana Island lẹyin tí ile alaja meje wo ni agbegbe naa.
Sanwo-Olu pa asẹ yii lasiko to ṣe abewo si ibi ti ile alaja meje ti dawo ni ọsẹ melo kan sẹyin.
Ni agbegbe 310 close, Gomina ni kí wọn da ile alaja meji wo nítorí ìjọba ko bu wọlu awọn ile ọhun.
Bakan naa ni 306 close, Gomina ni da ile alaja meji to kọju si arawọn wo nitori abẹ ina mọnamọna ati omi ni ile ọhun wá.
Gomina ni asise awọn abanikọle ati awọn araalu tí wọn n wa owo ojiji lo fa bí ile alaja meje se da wo.
Bakan naa Gomina bu ẹnu atẹlu bi ileeṣẹ ijọba apapọ to n risi isẹ ati ile gbe fun bí wọn ṣe gba lati se afikun si agbegbe Banana Island.
Gomina ni gbogbo awọn osisẹ ìjọba to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa ni wọn yoo ri ijiya labẹ ofin.
Àwọn èèyàn tó ti kú lẹ́yìn tí oníwàású ní kí wọ́n febi pa ara wọn láti pàdé Jesu wọ 73
Wo àwọn orílẹ̀ èdè tó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó àwọn ènìyàn wọn kúrò ní Sudan

Oríṣun àwòrán, Reuters
Iléeṣẹ́ ológun orílẹ̀ èdè Sudan ti kéde pé àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní dá àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè UK, US, France àti China tó wà ní orílẹ̀ èdè àwọn padà sí ìlú wọn láìpẹ́.
Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun orílẹ̀ èdè náà, Fattah al-Burhan tó kéde ọ̀rọ̀ náà ní àwọn ti fẹnukò láti ri pé àwọn ènìyàn náà padà sí orílẹ̀ èdè wọn pẹ̀lú gbogbo ìfaǹfà tọ ń lọ lọ́wọ́ lórílẹ̀ èdè náà.
Ṣaájú ni gbogbo ìgbìyànjú ìjọba UK láti kọ àwọn òṣìṣẹ́ àti àwọn ènìyàn wọn tó wà ní orílẹ̀ èdè ọ̀hún já sí pàbó.
Àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ ológun fi síta ní ọkọ̀ òfurufú iléeṣẹ́ ológun ni wọ́n máa fi kó àwọn ènìyàn náà kúrò ní Khartoum, tí ń ṣe olú ìlú Sudan.
Ìjọba UK ní àwọn ń sa gbogbo ipá àwọn láti ri pé àwọn òṣìṣẹ́ àwọn tó wà ní Khartoum ni wọ́n kó kúrò níbẹ̀.
Olóòtú ìjọba UK, Rishi Sunak ṣe ìpàdé pàjáwìrì ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta láti mọ ọ̀nà tí wọn yóò gbà láti fi kó àwọn ènìyàn wọn kúrò.
Bákan náà ni orílẹ̀ èdè Saudi Arabia kéde pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti kó àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè wọn àti orílẹ̀ èdè tó súnmọ́ wọn kúrò ní Sudan.
Pápákọ̀ òfurufú tó wà ní Khartoum ló ti wà ní títí pà èyí tó dí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè bíi UK, US àtàwọn mìíràn lọ́wọ́ láti kó àwọn ènìyàn wọn kúrò.
Àjọ ètò ìler àgbàyé, WHO ní kò dín ní ènìyàn 400 tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní Sudan láti ìgbà tí wàhálà ti bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn olórí ológun lórí bí wọ́n yóò ṣe máa ṣètò orílẹ̀ èdè náà.
Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN ní ó ti tó ènìyàn 20,000 tó fi mọ́ àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé ló ti sá kúrò ní Sudan lọ sí Chad.
Mi ò ní ẹ̀mí láti gbé pẹ̀lú ìyàwó mẹ́fà láàfin Ooni – Olorì Silekunola
Ẹ̀yin ọmọ Naijiria ni Sudan, ẹ ṣì dúró sọ́hun o! Ìdí tá ò fi lè kóo yín wálé lásìkò yìí rèé – Ijoba
A kìí ṣe oní jìbìtì ní'lé Akuji, Mòlẹ́bí Alfa Ràfíu oní POS tí wón sèèsì fi N280m ránsẹ́ si àkántì rẹ̀ n'Ilorin fi igbe ta!
Ìjàmbá ọkọ̀ gbẹ̀mí ènìyàn kan, àwọn mẹ́ta mìíràn farapa lẹ́yìn ìrun yídì ní Ilorin

Oríṣun àwòrán, Federal Road Safety Corps/Facebook
Àkọlé àwòrán, Ijamba Ọkọ Awọn eeyan mẹrin kan ti wọn ti yidi ilu Ilorin bọ ni wọn ṣe agbako ijamba ọkọ ayọkẹlẹ eyi ti o ya lọ ba wọn lagbegbe Balogun Fulani ni ilu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara.
Ijamba ọhun lo gbẹmi ẹnikan ti awọn mẹta yooku si farapa yanayana.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣalaye wi pe,awọn mẹrin ọhun ni wọn wa lori okada ki ọkọ ayọkẹlẹ naa to ya lọ bawọn ti ẹnikan si padanu ẹmi rẹ ninu ijamba naa.
Ọkunrin ọhun to padanu ẹmi rẹ ninu ijamba naa ni wọn pe ni Suraju lati agbo ile Alamo, Okelele, Ilorin.
Iroyin ni Suraju gbẹmi mi lẹyin nigba ti wọn fi maa gbe de ile iwosan kan lẹyin iṣẹlẹ naa.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe fidi rẹ mulẹ, wọn ti sin Suraju si itẹ awọn musulumi to wa ni agbegbe Osere.
Meji lara awọn mẹta to farapa nibi isẹlẹ ọhun lo ti wa ni ile iwosan ijọba to wa ni Surulere Ilorin, ti ẹni kẹta si n gba itọju ni ile awọn to n to egungun ni agbegbe Dada.
Ọga agba ajọ to n ri si igokegbodo ọkọ ni Naijiria, FRSC ni ipinlẹ Kwara, Frederick Ogidan ni ko si ẹnikẹni to tii fi iṣẹlẹ naa to awọn leti lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.
Owolabi Ajasa rèé láì wọ aṣọ Ọlọ́pàá lórí ètò "Ṣóo láyà", ẹ wo bóyá ó Yorùbá rẹ̀ dájú tàbí ó gbé e gbági
Ìjọba mi ti mú ìlérí ṣẹ pẹ̀lú ètò ìdìbò tó kẹsẹ járí....Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari/Facebook
Àkọlé àwòrán, Aarẹ Buhari Aarẹ Muhammadu Buhari ti ki awọn musulumi lori ayeye Eid-ul-Fitr eyiti o waye lẹyin opin awẹ Ramadan ọlọgbọn ọjọ.
Aarẹ Buhari nigba to oun sọrọ lori abajade awọn esi eto idibo ọdun 2023,o ni yoo wa ni akọsilẹ gẹgẹbi ọkan ninu awọn eto idibo ti ko lọwọ ijọba ninu.
Ninu atẹjade ti alakoso ẹka ibaraẹnisọrọ aarẹ Buhari Garba Sheu filede lorukọaarẹ,o ni "awọn esi abajade ninu eto idibo ọdun yii fi awọn ileri ti mo ṣe ṣaaju lati ri wi pe, eto idibo labẹ iṣakoso mi yoo kẹsẹ jari".
Aarẹ Buhari ni " eto idibo to ni alafia ni ọpa itẹgun si ijọba awarawa ti yo mu idagbasoke wa,nitori ti a ba tẹri ifẹ awọn eeyan baa,ijọba awarawa ko ni kẹsẹ jari".
“Idibo naa han gbangba gbangba wi pe ko si ọwọ ijọba nibẹ nitori wi pe,awọn ọmọ ẹgbẹ mi kọkan fìdi rẹmi". Lori ãwẹ Ramadan, Aare Buhari ki awọn Musulumi ku oriire aṣeyọri awẹ to jẹ ọranyan fun awọn musulumi".
Buhari gbadura si Ọlọhun lati san ẹsan fun awọn Musulumi fun irubọ wọn ni akoko aawẹ.
Aare Buhari gba wọn ni imọran pe "ko yẹ ki a gbagbe awọn ẹkọ pataki Ramadan, ki ibasepo wa pẹlu awọn alaini ati awọn talaka to wa ni awujọ tesiwaju sii".
Olówó fi owó ra eyín ikú - Portable figbe ta torí ìlera tó dé bá a