Aṣojú ìjọba Nàìjíríà nílẹ̀ Olómìnira Benin gba àlejò ọkùnrin tó gun ọ̀kadà láti London wá sí Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Adewoyin Adeyinka
Manigbagbe ni ọjọ Aje, ọjọ kẹfa oṣu Keje ọdun 2026 yii jẹ ninu itan, pẹlu bi Arabinrin Adeola Mopelola Ibrahim to jẹ Aṣoju ijọba Naijiria nilẹẹ Benin, ṣe gba alejo Ọgbẹni Olatunji Emmanuel Okedeyi, to gun ọkada lati ilu London, lorilẹede UK lọ si Benin to si pada de si Naijiria.
Lasiko ti Okedeyi gunlẹ si Benin lo ṣabewo sileeṣẹ aṣoju ijọba Naijiria naa pẹlu àwon ikọ to wa pade rẹ.
Ki lo mu Okedeyi gun ọkada lati London wa silẹ Adulawọ?
Gẹgẹ bi Olatunji Emmanuel Okedeyi, ọmọ bibi ilu Ibadan to rin irin ajo naa ṣe ṣalaye, o ni idi toun fi gun alupupu lati UK wa si Naijiria ko ṣẹyin ati kowo jọ fun igbogunti arun rọmọlapa-rọmọ lẹsẹ (Polio) lagbaaye.
Olatunji sọ pe ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ni oun ni lọkan lati fi irinajo iyanu naa ko jọ, ki arun naa le kasẹ nilẹ patapata lagbaaye.
Ọkunrin ti ewu kun ori rẹ pẹlu ogbó naa ṣalaye pe ko dẹrun lati gun ọkada lati ilẹ alawọ funfun wa si ilẹ Adulawọ, nitori baaluu ni kaluku fi n ta kọṣọ lati ilẹ okeere si apa ibomiran.
Ṣugbọn nitori eto ọmọniyan ti oun gbe dani lo ni o jẹ koun gbe irinajo yii gba ilana ọkada gigun.
O ni bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ iṣoro ati ijakulẹ loun ba pade ninu irinajo naa, nigbẹyin, Oluwa ni ko ja si irọrun.
Ninu ọrọ Adeola Mopelola Ibrahim, Aṣoju ijoba Naijiria nilẹẹ Benin, o ki Okedeyi ku irin nla naa lorukọ Aare Bola Tinubu, ati lorukọ gbogbo awon oṣiṣẹ nileeṣẹ naa.
Mopelola gboriyin fun arinrinajo naa, o si ki i ku oriire fun ifẹ ọmọniyan to ni lọkan to jẹ ko gbe iru igbesẹ bayii.
Aṣoju Naijiria ni Benin tẹsiwaju pe ki arinrinajo naa ma ṣe ro pe ko si ere ninu ohun to ṣe yii.
O ni ẹsan rere n bẹ fun eni ti ko mọ ti ara rẹ nikan, amọ to fi ifẹ ẹlomiran sọkan.
O wa rọ gbogbo eeyan lati wo awokọṣe Ogbeni Olatunji Emmnuel fi ṣe aye ire.
Ọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii ni Olatunji Emmanuel Okedeyi gbera kuro niluu London.
Awọn orilẹede to gba kọja ninu irinajo naa ko too de Benin ni France - Spain - Morroco - Mauritania - Senegal - Guinea Bissau - Gambia - Guinea Conakry - Cote d'Ivoire - Ghana – Togo.
Togo lo gba de Benin Republic.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ keje oṣu Keje lo si balẹ si Naijiria, nibi ti Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti gba a lalejo.
Irinajo ti Okedeyi rin naa jẹ kilomita ẹgbẹrun mejila ati igba(12,200-kilometer).
Okedeyi tawọn eeyan tun maa n pe ni Captain, ni Aarẹ adiboyan ẹgbẹ Rotary Club of Mushin, niluu Eko.
Irinajo naa lo pe ni "London to Lagos: Two Wheels, One Mission to End Polio."



























