Ìjìyà tó bá tọ́ sí agbésùnmọ̀mí la máa fún ṣọ́jà tó bá ń dúró de àṣẹ kó tó pa wọ́n- Mínísítà ètò ààbò

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

"Bi wọn ba ti ran ọ lọ sibi iṣẹ, ma ṣe duro de ẹnikẹni lati yinbọn mọ agbesunmọmi tabi agbebọn ti o ba ri.

" Ẹnikẹni to ba kọ lati pa bandiiti tabi agbesunmọmi, to ni oun n duro de aṣẹ, a maa ṣe oun naa bii bandiiti ni.''

Minisita to n ri si ọrọ aabo lorilẹede Naijiria,Ọgagun Christopher Musa, lo sọrọ yii fawọn ologun nipinlẹ Sokoto l''Ọjọru.

Ọgagun Musa sọrọ naa lasiko ti wọn n pin awọn ọkọ akọtami fawọn ẹka alaabo nipinlẹ naa lati ran eto aabo lọwọ.

"Mo fẹẹ tun un sọ fun gbogbo ọmọ ologun pata, bi wọn ba ti le ran yin jade sibi kan lati ṣiṣẹ, ẹ ma ṣe tun duro de aṣẹ lati ọdọ ẹnikẹni mọ lati yinbọn mọ bandiiti tabi agbesunmọmi."

Bẹẹ ni minisita naa ṣalaye pẹlu afikun pe ojuṣe awọn ologun ni lati koju awọn agbesunmọmi bi wọn ba ri wọn.

"Ojuṣe ologun ni lati ri i pe wọn pa agbesunmọmi, wọn ko gbọdọ gba agbesunmọmi laye lati pa wọn"

Ni itẹsiwaju ọrọ Ọgagun Christopher Musa nibi ti wọn ti pin awọn nnkan iranwọ ogun naa, o ṣalaye pe ojuṣe agbofinro ni lati tete mu bandiiti balẹ, ki i ṣe pe ki wọn duro ti awọn ẹni ibi naa yoo fi pa ọmọ ogun.

O fi kun un pe owo araalu ni ijọba fi ra awọn nnkan iwulo ogun ti wọn pin fawọn ẹka nipinlẹ Sokoto lati fi da aabo bo araalu.

O ni ijọba ra wọn lati fi ri i pe ọkan araalu balẹ ni.

Ọgagun Musa sọ pe idi niyẹn ti awọn ologun fi gbọdọ tete mu ẹni to ba fẹ da wahala silẹ lagbegbe rẹ balẹ nibikibi ti wọn ba ti ri i.

O wa fi kun alaye naa pe bi wọn ba ti n tẹle aṣẹ pipa agbesunmọmi yii, ki wọn maa fi ti ọmọluabi ati ọgbọn akọṣẹmọṣẹ kun un.

Ọgagun Musa sọ pe ibọn yinyin ati ija pẹlu agbebọn nikan ko to, bi ko ṣe pe ki wọn ri I pe wọn ko ṣi aṣẹ naa lo.

O ni ki wọn ma ṣe da oju ibọn kọ araalu ti ko ṣẹ o.

Bakan naa lo pe fun ajọṣepọ laarin awọn ẹṣọ alaabo atawọn eeyan agbegbe ibilẹ, o ni ki araalu tete maa ta awọn agbofinro lolobo lori ohun ifura ti won ba kẹẹfin.

Ọgagun naa fi awọn olugbe ipinlẹ Sokoto atawọn ọmọ Naijiria lapapọ lọkan balẹ, o ni ijọba apapọ ko yẹsẹ ninu ipese aabo, ninawo lori irinṣẹ ogun ati bẹẹ bẹẹ lọ fun aabo to peye ni Naijiria.